7 Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwà-kúwà sí aláìní baba àti opó.
8 Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkúlò.
9 Nínú rẹ ni àwọn ayanijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́.
10 Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọla fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn ti o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́.
11 Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ ṣe, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀.
12 Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; Ìwọ gba èlé lọ́pọ̀pọpọ̀ láti mú aláìsòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé ẹ̀ mi; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
13 “ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárin yín.