15 Bákan náà ni àwa yóò mú àgùntàn kan láti inú agbo ẹran tí ó jẹ́ igba láti inú kanga omi pápá oko tútù tí Ísírẹ́lì. Ìwọ̀nyí ni wọn yóò lò fún àwọn ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ẹbọ sísun àti ìdàpọ̀ ọrẹ ẹbọ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Ọba sọ.
16 Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ aládé ni Ísírẹ́lì.
17 Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àṣè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ ìsìnmi ni gbogbo àjọ ilé Ísírẹ́lì. Oun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Ísírẹ́lì.
18 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọba wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́.
19 Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ilẹkùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ilẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú.
20 Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ kéje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run.
21 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àṣè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà.