24 “Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù.’ ”
25 Mósè sì dìde lọ bá Dátanì àti Ábírámù àwọn olórí Ísírẹ́lì sì tẹ̀lé.
26 Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, “Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
27 Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù. Dátanì àti Ábírámù jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn.
28 Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé Olúwa ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe.
29 Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yóòkù, a jẹ́ pé kì í ṣe Olúwa ló rán mi.
30 Ṣùgbọ́n bí Olúwa bá ṣe ohun túntún, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láàyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn Olúwa.”