19 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (40,500).
20 Ẹ̀yà Mánásè ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Mánásè ni Gàmálíélì ọmọ Pedasúrì.
21 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba (32,200).
22 Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni yóò tẹ̀ lé e. Olórí Bẹ́ńjámínì ni Ábídánì ọmọ Gídíónì.
23 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tadínlógún ó lé egbéje (35,400).
24 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Éfúráímù, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàdọ́ta-ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
25 Ní ìhà àríwá, ni ìpín Dánì yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olóri Dánì ni Áyésérì ọmọ Ámíṣádáyì.