25 Ní ìhà àríwá, ni ìpín Dánì yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olóri Dánì ni Áyésérì ọmọ Ámíṣádáyì.
26 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700).
27 Ẹ̀yà Ásérì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ásérì ni Págíélì ọmọ Ókíránì.
28 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).
29 Ẹ̀yà Náfítanì ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Náfítanì ni Áhírà ọmọ Énánì.
30 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-egbéje (53,400).
31 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rún-ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.