6 Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì mú obìnrin Mídíánì wá ṣíwájú ojú Mósè àti gbogbo ìpéjọ ti Ísírẹ́lì wọ́n sì ń sunkún ní àbáwọlé Àgọ́ Ìpàdé.
7 Nígbà tí Fínéhásì, ọmọ Élíásárì, ọmọ Árónì, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìpéjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.
8 Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Ísírẹ́lì yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Ísírẹ́lì àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró;
9 ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-àrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá. (24,000)
10 Olúwa sì tún sọ fún Mósè pé,
11 “Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà, ti yí ìbinú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrin wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.
12 Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.