12 Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹní tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má baà kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́.
13 Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín.
14 Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jọ́dánì, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kénánì tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí.
15 Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún àlejò àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrin wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sá lọ ṣíbẹ̀.
16 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pá, apànìyàn náà.
17 Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà.
18 Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ ọ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni; pípa ní a ó pa apànìyàn náà.