Onídájọ́ 19:18-24 BMY

18 Ọmọ Léfì náà dá a lóhùn pé, “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbégbé tí ó sápamọ́ ní àwọn òkè Éfúráímù níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, èmi sì ń lọ sí ilé Olúwa nísinsìn yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀.

19 Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ-èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.”

20 “Mo kí ọ kú ààbọ̀ sí ilé mi,” ni ìdáhùn ọkùnrin arúgbó náà. “Èmi yóò pèṣè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ìta.”

21 Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹṣe wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu.

22 Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Bélíálì kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kún; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.”

23 Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹyin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.

24 Kíyèsí i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúndíá, àti àlè rẹ̀; àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwa òmùgọ̀ yìí sí.”