1 Nínú ìwé mi ìṣáájú, Tèófilọ́sì, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́
2 Títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn àpósítélì tí ó yàn
3 Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láàyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run.
4 Nígbà kan, bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerúsálémù, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ẹ̀bùn tí Baba mi se ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi.
5 Nítorí Jòhánù fi omi bamitíìsì yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín.”
6 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọ pọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Ísírẹ́lì bí?”
7 Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe ti yín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkárarẹ̀.