19 Bí Pétérù sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.
20 Njẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kọminú ohunkohun: nítorí èmi ni ó rán wọn.”
21 Nígbà náà ni Pétérù sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí tẹ̀ ti ẹ fi wá?”
22 Wọ́n sì wí pé, “Kọ̀nẹ́líù balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ́ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ ańgẹ́lì mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”
23 Nígbà náà ni ó pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.Níjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, nínú àwọn arákùnrin ní Jopa sì bá a lọ pẹ̀lú.
24 Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesaríà, Kọ̀nélíù sì ti ń rétí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.
25 Ó sì ṣe bí Pétérù ti ń wọlé, Kọ̀nélíù pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un.