7 Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Pétérù: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’
8 “Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘Àgbẹdọ̀, Olúwa! nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láí.’
9 “Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kéjì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’
10 Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.
11 “Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesaríà sí mi.
12 Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà:
13 Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí ańgẹ́lì kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Pétérù;