10 Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ ìkínní àti ìkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tikararẹ̀ sí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
11 Nígbà tí ojú Pétérù sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán ańgẹ́lì rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Héródù àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń rétí!”
12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Johánù, tí àpélè rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ pejọ sí, tí wọn ń gbàdúrà.
13 Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Ródà wá láti dáhùn.
14 Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Pétérù, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sí sọ pé, Pétérù dúró ní ẹnu-ọ̀nà.
15 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Ańgẹ́lì rẹ̀ ni!”
16 Ṣùgbọ́n Pétérù ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n.