Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12:6-12 BMY

6 Ní òru náà gan-an ti Héródù ìbá sì mú un jáde, Pétérù ń sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀sọ́ sí wà lẹ́nu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà.

7 Sì wò ó, ańgẹ́lì Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ́ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Pétérù pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Pétérù.

8 Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Pétérù sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!”

9 Pétérù sì jáde, ó ń tọ ọ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣèbí òun wà lójú ìran.

10 Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ ìkínní àti ìkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tikararẹ̀ sí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.

11 Nígbà tí ojú Pétérù sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán ańgẹ́lì rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Héródù àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń rétí!”

12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Johánù, tí àpélè rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ pejọ sí, tí wọn ń gbàdúrà.