1 Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Áńtíókù; Bánábà àti Síméónì tí a ń pè ni Nígérì, àti Lúkíọ́sì ará Kírénè, àti Mánáénì (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Hẹ́ródù Tétírákì) àti Ṣọ́ọ̀lù.
2 Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!”
3 Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.
4 Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn mẹ́jẹ̀èjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀-ojú omi lọ sí Sáípúrọ́sì.
5 Nígbà ti wọ́n sì wà ni Sálámísì, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní sínágọ́gù àwọn Júù. Jòhánù náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn.