17 Ọlọ́run àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì, apá gíga ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,
18 ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrú fún ìwà wọn ní ijù,
19 nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kénááni, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.
20 Gbogbo èyí sì sẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) ọdún. Lẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídájọ̀ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samueli wòlíì.
21 Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì bèèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, ọkùnrin kan nínú ẹ̀ya Bẹ́ńjámínì, fún ogójì ọdún.
22 Nígbà ti ó sì mú Ṣọ́ọ̀lù kúrò, ó gbé Dáfídì dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dáfídì ọmọ Jésè ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’
23 “Láti inú irú ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jésù Olugbàlà dìde fún Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìlérí.