28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pílátù láti pá a.
29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀we nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.
30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú,
31 Ó sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Gálílì wá sí Jerúsálémù, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsìn yìí fún àwọn ènìyàn.
32 “Àwa sì mú ìyìn rere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,
33 Èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jésù dìde: Bí a sì ti kọwé rẹ̀ nínú Sáàmù kejì pé:“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;lónìí ni mo bí ọ.’
34 Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyí pé:“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dáfídì, tí ó dájú.’