6 Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Páfọ̀, wọ́n rí ọkùnrin kan, oṣó, wòlíì èké, Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Baa-Jésù.
7 Ó wà lọ́dọ̀ Ségíù Páúlúsì baálẹ̀ ìlú náà, amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
8 Ṣùgbọ́n Élímù oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa báalẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́.
9 Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti a ń pè ni Pọ́ọ̀lù, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Ẹ́límù, ó sì wí pé,
10 “Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà-ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?
11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí òòrùn ní sáà kan!”Lójúkan náà ìkunkùn àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ.
12 Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.