9 Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti a ń pè ni Pọ́ọ̀lù, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Ẹ́límù, ó sì wí pé,
10 “Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà-ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?
11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí òòrùn ní sáà kan!”Lójúkan náà ìkunkùn àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ.
12 Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.
13 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Páfòsì wọ́n wá sí Págà ni Pàmífílíà: Jòhánù sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerúsálémù.
14 Nígbà ti wọ́n sì là Págà kọjá, wọ́n wá sí Pìsìdíà ní Áńtíókù. Wọ́n sì wọ inú sínágọ́gù ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.
15 Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”