6 wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lísírà, àti Dábè, àwọn ìlú Líkáóníà àti sí agbégbé àyíká.
7 Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìyìn rere.
8 Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lísírà, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí.
9 Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá.
10 Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánsán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.
11 Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Líkáóníà, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!”
12 Wọn sì pe Bánábà ni Ṣeusi àti Pọ́ọ̀lù ni Hamisi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ síṣọ.