8 Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lísírà, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí.
9 Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá.
10 Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánsán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.
11 Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Líkáóníà, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!”
12 Wọn sì pe Bánábà ni Ṣeusi àti Pọ́ọ̀lù ni Hamisi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ síṣọ.
13 Àlùfáà Júpítérì, ẹni ti ilé òrìsà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn, ó sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu-ibode láti rúbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn àpósítélì wọ̀nyí.
14 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn àpósítélì Bánábà àti Pọ́ọ̀lù gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: