33 Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a ṣi bamitíìsì rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà.
34 Ó sì mú wọn wá ṣí ilé rẹ̀, ó sì gbé ounjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.
35 Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà ṣílẹ̀.”
36 Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Pọ́ọ̀lù, wí pé, “Àwọn onídájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da yín ṣílẹ̀: ǹjẹ́ nisinsìnyìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”
37 Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bí, àwa ẹni tí ì ṣe ara Róòmù: ṣe nísinsìnyìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde nikọ̀kọ̀? Àgbẹdọ̀! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkara wọn wá mú wa jáde!”
38 Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàjọ́: ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù ni wọ́n.
39 Wọ́n sì wá, wọ́n sìpẹ̀ fún wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà.