26 Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.
27 Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán; ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ.”
28 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà ti ará Éfésù!”
29 Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ipa fa Gáíù àti Árísítaríkù ara Makedóníà lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn-àjò.
30 Nígbà ti Pọ́ọ̀lù sì ń fẹ́ wọ àárin àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un.
31 Àwọn olórí kan ara Éṣíà, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ibi-ìṣeré náà.
32 Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíran: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọ pọ̀.