16 Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joeli:
17 “ ‘Ní ìkẹyìn ọjọ́, Ọlọ́run wí pé,Èmi yóò tú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo,àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran,àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá;
18 Àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi obìnrin,ni Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi jáde ni àwọn ọjọ́ náà:wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀;
19 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run,àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀;ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;
20 A yóò sọ òòrùn di òkùnkùn,àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.
21 Yóò sì ṣe pé ẹnikẹ́ni tí ó bá peorúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’
22 “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jésù tí Násárẹ́tì, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín, bí ẹ̀yin tíkárayín ti mọ̀ pẹ̀lú.