18 Àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi obìnrin,ni Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi jáde ni àwọn ọjọ́ náà:wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀;
19 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run,àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀;ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;
20 A yóò sọ òòrùn di òkùnkùn,àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.
21 Yóò sì ṣe pé ẹnikẹ́ni tí ó bá peorúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’
22 “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jésù tí Násárẹ́tì, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín, bí ẹ̀yin tíkárayín ti mọ̀ pẹ̀lú.
23 Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á.
24 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí díde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dì í mú.