26 Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀:pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.
27 Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà-òkú,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni-Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.
28 Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’
29 “Ará, èmí lè sọ fún yin pẹ́lú ìgboyà pé ní ti Dáfídì baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí.
30 Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.
31 Ní rírí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kírísítì, pé a kò fi ọkan rẹ̀ sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.
32 Jésù náà yìí ni Ọlọ́run ti jí díde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.