31 Ní rírí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kírísítì, pé a kò fi ọkan rẹ̀ sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.
32 Jésù náà yìí ni Ọlọ́run ti jí díde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.
33 A ti gbé ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsìyìí sítá.
34 Nítorí Dáfídì kò gókè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ wí pé,“ ‘Olúwa wí fún Olúwa mi pé:“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
35 títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹdí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’
36 “Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jésù náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, se Olúwa àti Kírísítì.”
37 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Pétérù àti àwọn àpósítélì yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe”