5 Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerúsálémù.
6 Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ nínú ìdàmú, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀.
7 Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Gálílì kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́?
8 Èé ha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀?
9 Àwọn ará Pátíríà, àti Médísì, àti Élámù; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamíà, Júdíà, àti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àti Ásíà.
10 Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè; àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù.
11 (àti àwọn Júù àti àwọn tí a tipa ẹ̀sìn sọ di Júù); Àwọn ara Kírétè àti Árábíà; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ́rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.”