7 Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Gálílì kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́?
8 Èé ha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀?
9 Àwọn ará Pátíríà, àti Médísì, àti Élámù; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamíà, Júdíà, àti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àti Ásíà.
10 Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè; àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù.
11 (àti àwọn Júù àti àwọn tí a tipa ẹ̀sìn sọ di Júù); Àwọn ara Kírétè àti Árábíà; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ́rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.”
12 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n aì wá rìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?”
13 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmìíràn ń sẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì titun.