1 Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ ṣí Makedóníà.
2 Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ pupọ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Gíríkì.
3 Ó sì dúró níbẹ̀ ní osù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àtibá ọkọ̀-ojú-omi lọ sí Síríà, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedóníà padà lọ.
4 Sópátérù ará Béríà ọmọ Páríù sì bá a lọ dé Éṣíà; àti Sékúńdù; àti Gáíúṣì ará Dábè, àti Tìmótíù; ará Éṣíà, Tíkíkù àti Tírófímù.
5 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Tíróáṣì.
6 Àwa sì síkọ̀ láti Fílípì lọ lẹ́yìn ọjọ àkàrà àìwú, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróáṣì ni ijọ́ méje.
7 Ọjọ́ ìkínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Pọ́ọ̀lù sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ijọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárin ọ̀gànjọ́.