1 “Ẹ̀yin ará àti baba, ẹ gbọ́ tí ẹnu mi nísinsìnyìí.”
2 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Árámáíkì, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́.Nígbà náà ni ó wí pé:
3 “Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tásọ́sì ìlú kan ní Kílíkíà, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì jẹ́ onítara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní.
4 Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin àtobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú,
5 àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakùnrin wọn ní Dámásíkù láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerúsálémù, láti jẹ wọ́n níyà.
6 “Bí èmi tí súnmọ́ etí Dámásíkù níwọ̀n ọjọ́kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká.