Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23:14-20 BMY

14 Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Pọ́ọ̀lù.

15 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí-ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”

16 Nígbà tí ọmọ arabínrin Pọ́ọ̀lù sí gbúrò ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù.

17 Pọ́ọ̀lù sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí-ogun lọ: nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”

18 Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí-ogun.Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Pọ́ọ̀lù òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sí bẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”

19 Olórí-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”

20 Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ sọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbimọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ bèèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.