17 Pọ́ọ̀lù sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí-ogun lọ: nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”
18 Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí-ogun.Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Pọ́ọ̀lù òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sí bẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”
19 Olórí-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”
20 Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ sọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbimọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ bèèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.
21 Nítorí náà má ṣe gbọ́ ti wọn: nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsìn yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”
22 Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”
23 Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ ṣí Kesaríà, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹ́ta òru.