1 Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mélítà ni a ń pè eré-kùṣù náà.
2 Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn alàìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù.
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sa ìdí ìwọ̀nwọ̀n-igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.
4 Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú àpànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láàyè.”
5 Òun sì gbọn ẹranko náà sínu iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.