16 Nígbà tí a sì dé Róòmù, olórí àwọn ọmọ ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀sọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láàyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń sọ́ ọ.
17 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù pe àwọn olórí Júù jọ: nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti se pé èmi kò se ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, ṣíbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Róòmù lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerúsálémù wá.
18 Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi.
19 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù sọ̀rọ̀ lòdì sí i, èyí sún mí láti fi ọ̀ràn náà lọ Késárì, kì í ṣe pé mo ní ẹ̀sùn kan láti fi kan àwọn ènìyàn mi.
20 Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”
21 Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò rí ìwé gbà láti Jùdíà nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ.
22 Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”