14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin sẹ́ Ẹni-Mímọ́ àti Olóòtọ̀ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín.
15 Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́.
16 Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jésù àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.
17 “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe.
18 Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti se ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kírísítì rẹ̀ yóò jìyà.
19 Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
20 àti kí ó baà lè rán Kírísítì tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jésù.