33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbérò láti pa wọ́n.
34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gàmálíẹ́lì, Farisí àti àmofìn, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn àpósítélì bì sẹ́yìn díẹ̀.
35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyèsí ara yín lóhun tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí.
36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Téúdà dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pá a; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán.
37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Júdà ti Gálílì dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì fa ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká.
38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, Ẹ gáfárà fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣúbu.
39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣúbu; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà”