2 Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábílì.
3 Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí.
4 Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”
5 Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti Fílípì, àti Pírókórù, àti Níkánórù, àti Tímónì, àti Páríménà, àti Níkólásì aláwọ̀se Júù ara Ańtíókù.
6 Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Àpósítélì; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.
7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerúsálémù, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.
8 Sítéfánù tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrin àwọn ènìyàn.