16 A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣékémù, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Ábúráhámù rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Ámórì ní Sékémù ní iye-owó wúrà kan.
17 “Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Ábúráhámù sẹ kù dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbérù si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Íjíbítì.
18 Ṣùgbọ́n ọba mị̀íràn, ẹni tí kò mọ ohunkóhun nípa Jósẹ́fù, di alásẹ lórí ilẹ̀ Íjíbítì.
19 Òun náà ni ó ṣe àrékekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ-ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.
20 “Ní àkókò náà ni a bí Mósè, ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀.
21 Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀.
22 A sì kọ́ Mósè ni gbogbo ọgbọ́n ara Íjíbítì, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.