26 Ní ọjọ́ kejì Mósè yọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun ì bá sí parí rẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; è é ṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
27 “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ tì Mósè sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ jẹ olórí àti onídàjọ́ wa?
28 Àbí ìwọ ń fẹ́ pa mi gẹ́gẹ́ bí o ti pa ará Íjíbítì lánàá?’
29 Mósè sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Mídíànì, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.
30 “Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Mósè ní ijù, ní òkè Sínáì, nínú ọ̀wọ́ iná ìgbẹ́.
31 Nígbà tí Mósè sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i,
32 Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù,’ Mósè sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dàṣà láti wò ó mọ́.