36 Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Íjíbítì, àti ni òkun pupa, àti ni ihà ní ogójì ọdún.
37 “Èyí ni Mósè náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’
38 Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú ańgẹ́lì náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sínáì, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.
39 “Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì;
40 Wọ́n wí fún Árónì pé ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ ọ̀nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mósè yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’
41 Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rúbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn se.
42 Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:“ ‘Ẹ̀yin hà mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún miní ogójì ọdún ní ijù bí, Ìwọ ilé Ísírẹ́lì?