1 Sọ́ọ̀lù sì wà níbẹ̀, ó sì ní ohùn sí ikú rẹ̀.Ní àkókò náà, inúnibini ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerúsálémù, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Jùdíà àti Samaríà, àyàfi àwọn àpósítélì.
2 Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Sítéfánù lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀.
3 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù bẹ̀rè sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
4 Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo, wọn ń wàásù ọ̀rọ̀ náà.
5 Fílípì sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaríà, ó ń wàásù Kírísítì fún wọn.
6 Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ̀, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Fílípì ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkan kan fíyèsí ohun tí ó ń sọ.