11 Wọ́n bọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn.
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jésù Kírísítì, a bámítíìsì wọn.
13 Símónì tikararẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bámitíìsì rẹ̀, ó sì tẹ̀ṣíwájú pẹ̀lú Fílípì, ó wo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Fílípì ṣe, ẹnu sì yà á.
14 Nígbà tí àwọn àpósítélì tí ó wà ní Jerúsálémù sí gbọ́ pé àwọn ara Samaríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù Àti Jòhánù sí wọn.
15 Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́:
16 nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bá lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitíìsì wọn lórúkọ Jésù Olúwa ni.
17 Nígbà náà ni Pétérù àti Jòhánù gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.