24 Nígbà náà ni Símónì dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”
25 Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Pétérù àti Jòhánù padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì wàásù ìyìn rere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn Samaríà.
26 Ańgẹ́lì Olúwa sì sọ fún Fílípì pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerúsálémù lọ sí Gásà.”
27 Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsí, ọkùnrin kan ará Etiópíà, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọdọ̀ Káńdákè ọba-bìnrin àwọn ara Etiópíà, ẹni tí í se olórí ìsúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerúsálémù láti jọ́sìn,
28 Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà.
29 Ẹ̀mí sì wí fún Fílípì pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”
30 Fílípì si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà, Fílípì sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”