3 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù bẹ̀rè sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
4 Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo, wọn ń wàásù ọ̀rọ̀ náà.
5 Fílípì sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaríà, ó ń wàásù Kírísítì fún wọn.
6 Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ̀, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Fílípì ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkan kan fíyèsí ohun tí ó ń sọ.
7 Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúkùn-ún ni ó sì gba ìmúláradá.
8 Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
9 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Símónì, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaríà. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun.