35 Fílípì sí ya ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé-mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìn rere ti Jésù fún un.
36 Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitíìsì?”
37 Fílípì sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitíìsì rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jésù Kírísítì Ọmọ Ọlọ́run ni.”
38 Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Fílípì àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Fílípì sì bamitíìsì rẹ̀.
39 Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Fílípì lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.
40 Fílípì sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Ásótù, bí ó ti ń kọ́ja lọ, o wàásù ìyìn rere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesaríà.