6 Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ̀, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Fílípì ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkan kan fíyèsí ohun tí ó ń sọ.
7 Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúkùn-ún ni ó sì gba ìmúláradá.
8 Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
9 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Símónì, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaríà. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun.
10 Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ Ńlá.”
11 Wọ́n bọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn.
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jésù Kírísítì, a bámítíìsì wọn.