11 Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Júdà ní Òpópónà Tààrà, kí ó sì bèèrè ẹni tí a ń pè ni Ṣọ́ọ̀lù, ara Tásọ́sì, sá wò ó, ó ń gbàdúrà.
12 Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Ananíyà o wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”
13 Ananíyà sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúrò ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búrukú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerúsálémù.
14 Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhínyìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”
15 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Má a lọ; nítorí ohun-èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
16 Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”
17 Ananíyà sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù, ó sì wí pé, “Arákùnrin Sọ́ọ̀lù, Olúwa ni ó rán mi, Jésù tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ baà lè rìran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”