3 Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn.
4 Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé: mo sì gbọ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”
5 Ańgẹ́lì náà tí mo rí tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run:
6 Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láé láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, pé, “Kí a má ṣe jáfara mọ́.
7 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn ìpè ańgẹ́lì kéje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”
8 Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, “Lọ, gba ìwé tí a ṣí náà lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí o dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀.”
9 Mo sì tọ ańgẹ́lì náà lọ, mo sì wí fún pé, “Fún mi ní ìwé kékeré náà.? Ó sì wí fún mi pé, ‘Gbà kí o sì jẹ ẹ́ tan: yóò dàbí oyin.’ ”