3 Àmì mìíràn sì hàn lọ́run; sì kíyèsí i, dírágónì pupa ńlá kan, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, àti adé méje ní orí rẹ̀.
4 Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dírágónì náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.
5 Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè: a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀.
6 Obìnrin náà sì sá lọ sí ihà, níbi tí a gbé ti pèṣè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta.
7 Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mákẹ́lì àti àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun; dírágónì sì jagun àti àwọn angẹ́lì rẹ̀.
8 Wọ́n kò sì lè ṣẹ́gun; Bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọ̀run.
9 A sì lé dírágónì ńlá náà jáde, ejò láéláé ni, tí a ń pè ni Èṣù, àti Sàtanì, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.