11 Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí Ọ̀dọ́-Àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dírágónì.
12 Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn.
13 Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn.
14 Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fí fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè.
15 A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà.
16 Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti talákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn;
17 Àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní àmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí àmì orúkọ rẹ̀